Chapter 134 1 Ẹ kíyèsi i, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa , gbogbo ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa , tí ó dúró ní ilé Olúwa ní òru. 2 Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè sí ibi mímọ́, kí ẹ sì fi ìbùkún fún Olúwa . 3 Olúwa tí ó dá ọ̀run òun ayé, kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá.